Uncategorized

Kádàrá Kékèké

Láti parapọ pẹlú àwọn abánisèdè mi, n’go kọ gbogbo àwọn “kádàrá kékèké” l’énìí l’édè wa tó l’éwà, Yorùbá.

—Teju Cole (March 1, 2012)

 

1

N’ílùú Èkó, Peter fún arábirin kan l’óyun l’áìbèèrè. Pèlú pèlú, ó fúun l’óògùn láti b’oyún náà jé l’áìbèèrè. Èjè sì n’sun l’ára arábìnrin náà.

2

Ní Ọbádòré, onílé kan, Comfort, àti ọmọ rè arábìrin, Nwaka, fi irin lu Jenifer, aládùgbó wọn tí wọn fé lé dànù, ní ìlùkilù. Wọn féè lùú pa.

3

Wón fi Rejoice, 21, s’ójà ní Àbújá. Ìyàlénu ni fún ògá rè pé fún ‘ra rè l’ó jí N700,000 n’ínú ọjà náà. Kódà, Rejoice ti d’ẹléwòn báyìí.

4

A kì í gbọn tó “èmi-l’óni-í.” Ògbéni Nwachukwu tí wón gbà l’ólódẹ l’Óshòdì sọ’ra rè d’ọlópàá. Gbèhìn-gbèhìn, ọlópàá ló múu.

5

Wòólì kan láti Nigeria, Chikwui, ti d’ẹléwòn ní orílè èdè Malawi, l’éhìn t’ó gba owó l’ówó àwọn aládùúrà, láì ríran gégé bí ó ti s’èlérí.

6

Ìwádìí titun kan fi’hàn wípé l’áàrín àwọn òsìsẹ ìjọba ìlú Èkó, ọgórùún ti s’aláìsí, síbè-síbè wọn sì n’gbowó isé l’ósosù.

7

Ògbéni Ajogbeje ò gbó “má fi okoo mi dá ònà.” Nítorí isu on’ísu tó fé jÍ, ó yìn’bọn pa àgbè kan, Ògbéni Ajana, l’ókoo rè ní Ìkéré Èkìtì.

8

L’óòtó ni Edet Mbang je ènìyàn, sùgbón kò pa ènìyàn. Nítorí náà, léhìn ọdún méèdógún l’éwòn, Ilé Ẹjọ Gíga Nigeria ti sọ d’òmìnira.

9

Nítorí ìbínú àti ìkóríra tí ì ràn wòn nípa èkó ìwé, àwọn Boko Haram sun ilé èkó mérin ní iná ní ìlú Maiduguri.

______________

Teju Cole who works as an art historian is the author of bestselling novel Open City. His small fates can be found on twitter.